Ọdún 2025 ni ọdún Ejò. Nínú àṣà àwọn ará China, ejò náà("巳")kìí ṣe ọgbọ́n àti ìfaradà nìkan ló ṣàpẹẹrẹ, ṣùgbọ́n ó tún ṣàpẹẹrẹ ìdàgbàsókè àti ìsọdọ̀tun pẹ̀lú.
Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kìíní, ilé ẹ̀kọ́ CIS kún fún àyíká ayẹyẹ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́, àti àwọn òbí ṣe péjọ láti ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun ti àwọn ará China lábẹ́ àkọlé náà."Sì Sí Qiú Xīn, Suì Suì Yōu Xué" (Ìṣẹ̀dá tuntun àti ìtayọ ní gbogbo ọdún).